Add parallel Print Page Options

Bí ó bá tọ́ láti na ẹlẹ́bi, kí onídàájọ́ dá a dọ̀bálẹ̀ kí a sì nà án ní ojú u rẹ̀ ní iye pàṣán tí ó tọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀. Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ fún un ju ogójì pàṣán lọ. Bí ó bá nà án ju bẹ́ẹ̀ lọ, arákùnrin rẹ̀ yóò di ẹni ìrẹ̀sílẹ̀ ní ojú rẹ̀.

Read full chapter

29 Òfin kan kí ẹ̀yin kí ó ní fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ̀ ní àìmọ̀, àti fún àwọn ẹni tí a bí nínú àwọn ọmọ Israẹli, àti fún àlejò tí ń ṣe àtìpó.

30 “ ‘Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá mọ̀ ọ́n mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ yálà ó jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ yín tàbí àlejò, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ Olúwa, a ó sì gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀

Read full chapter

18 (A)Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin máa kíyèsára bí ẹ̀yin ti ń gbọ́: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní, lọ́wọ́ rẹ̀ ni a ó sì gba èyí tí ó ṣe bí òun ní.”

Read full chapter

26 (A)“Mo wí fún yín pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní, ni a ó fi fún, àti lọ́dọ̀ ẹni tí kò ní èyí tí ó ní pàápàá a ó gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.

Read full chapter