Add parallel Print Page Options

(A)Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Moabu,
    àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà,
Nítorí ó ti sun ún, di eérú,
    egungun ọba Edomu
Èmi yóò rán iná sí orí Moabu
    èyí tí yóò jó àwọn ààfin Kerioti run.
Moabu yóò sì kú pẹ̀lú ariwo
    pẹ̀lú igbe àti pẹ̀lú ìró ìpè
Èmi yóò ké onídàájọ́ rẹ̀ kúrò
    Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn ọmọ-aládé rẹ́ nínú rẹ̀,”
    ni Olúwa wí.

Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Juda,
    àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà
Nítorí wọn ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀
    wọn kò sì pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́
Nítorí àwọn òrìṣà ti sì wọ́n lọ́nà
    òrìṣà tí àwọn Baba ńlá wọn ń tẹ̀lé
Èmi yóò rán iná sí orí Juda
    èyí tí yóò jó àwọn ààfin Jerusalẹmu run.”

Ìdájọ́ tí yóò wá sórí Israẹli

Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Israẹli
    àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Wọ́n ta olódodo fún fàdákà
    àti aláìní fún bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì.
Wọ́n fi ẹsẹ̀ tẹ orí àwọn tálákà mọ́lẹ̀
    bí wọ́n ti ń tẹ erùpẹ̀ ilẹ̀
    tí wọ́n ko sì ṣe òtítọ́ si àwọn tí a ni lára
Baba àti ọmọ ń wọlé tọ wúńdíá kan náà
    Láti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́
Wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́bàá a pẹpẹ
    Lórí aṣọ tí wọ́n ti jẹ́ ẹ̀jẹ́
ní ilé òrìṣà wọn
    wọ́n sì mu ọtí tí wọ́n san fún ìtánràn.

“Mo pa àwọn ará Amori run níwájú wọn
    gíga ẹni tí ó dàbí igi kedari.
    Òun sì le koko bí igi óákù
mo pa èso rẹ̀ run láti òkè wá
    àti egbò rẹ̀ láti ìsàlẹ̀ wá.
10 Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá,
    mo sì sìn yín la aginjù já ní ogójì ọdún
    láti fi ilẹ̀ àwọn ará Amori fún un yín.

11 “Èmi sì tún gbé àwọn wòlíì dìde láàrín àwọn ọmọ yín
    àti láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín láti jẹ Nasiri
èyí kò ha jẹ́ òtítọ́ bí ará Israẹli?”
    ni Olúwa wí.
12 “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin fún àwọn Nasiri ní ọtí mu
    e sì pàṣẹ fún àwọn wòlíì kí wọ́n má ṣe sọtẹ́lẹ̀.

13 “Ní báyìí, èmi yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀
    bí kẹ̀kẹ́ tí ó kún fún ìtí ti í tẹ̀.
14 Ẹni tí ó yára bí àṣá kò ní rí ọ̀nà àbáyọ
    alágbára kò ní le è dúró lé agbára rẹ̀
    jagunjagun kì yóò le gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là
15 Tafàtafà kì yóò dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀
    bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó gún ẹṣin
    kì yóò gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là
16 Àní jagunjagun tí ó gbóyà jùlọ
    yóò sálọ ní ìhòhò ní ọjọ́ náà,”
    ni Olúwa wí.