Add parallel Print Page Options

Amoni ọba Juda

21 (A)Amoni jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjì. 22 Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Manase ti ṣe. Amoni rú ẹbọ sí gbogbo àwọn òrìṣà tí Manase baba rẹ̀ ti ṣe, ó sì sìn wọ́n. 23 Ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i baba rẹ̀ Manase. Kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Olúwa: ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ Amoni sì ń pọ̀ sì í.

24 Àwọn oníṣẹ́ Amoni dìtẹ̀ sí i. Wọ́n sì pa á ní ààfin rẹ̀. 25 Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Amoni, wọ́n sì mú Josiah ọmọ rẹ̀ jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Read full chapter