Add parallel Print Page Options

Manase ọba Juda

33 (A)Manase jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún márùn-dínlọ́gọ́ta. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa. Nípa títẹ̀lé ọ̀nà iṣẹ́ ìríra ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli rìn. Ó tún kọ́ àwọn ibi gíga tí baba rẹ̀ Hesekiah ti fọ́ túútúú. Ó sì gbé àwọn pẹpẹ dìde fún àwọn Baali ó sì ṣe àwọn ère Aṣerah. Ó foríbalẹ̀ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run ó sì sìn wọ́n. Ó kọ́ àwọn pẹpẹ sínú ilé Olúwa ní èyí tí Olúwa ti wí pé “Orúkọ mi yóò wà ní Jerusalẹmu títí láé.” Nínú ààfin méjèèje ti ilé Olúwa, ó kọ́ àwọn pẹpẹ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run Ó sì mú kí àwọn ọmọ ara rẹ̀ kí ó kọjá láàrín iná ní Àfonífojì Beni-Hinnomu, ó ń ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì ń lo àlúpàyídà, ó sì ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó ṣe ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú Olúwa láti mú un bínú.

Ó mú ère gbígbẹ́ tí ó ti gbẹ́ ó sì gbé e sínú ilé Olúwa, ní èyí tí Ọlọ́run ti sọ fún Dafidi àti sí ọmọ rẹ̀ Solomoni, “Nínú ilé Olúwa yìí àti ní Jerusalẹmu, tí mo ti yàn kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli, èmi yóò fi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé. Èmi kì yóò ṣí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli kúrò mọ́ ní ilẹ̀ náà tí èmi ti yàn fún àwọn baba ńlá yín, níwọ̀n bí wọ́n bá ṣe pẹ̀lẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí mo paláṣẹ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí gbogbo òfin, àṣẹ àti àwọn ìlànà tí a fún yín láti ọwọ́ Mose wá.” Ṣùgbọ́n Manase mú kí Juda àti àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu yapa, àti láti ṣe búburú ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ, àwọn tí Olúwa ti parun níwájú àwọn ọmọ Israẹli.

Read full chapter