Add parallel Print Page Options

Ìgbéraga, àṣeyọrí àti ikú Hesekiah

24 (A)Ní ọjọ́ wọ́n nì Hesekiah ṣe àárẹ̀, ó sì dójú ikú. Ó gbàdúrà sí Olúwa tí ó dá a lóhùn, tí ó sì fún un ní ààmì àgbàyanu. 25 Ṣùgbọ́n ọkàn Hesekiah ṣe ìgbéraga, kò sì kọbi ara sí i inú rere tí a fihàn án. Nítorí náà, ìbínú Olúwa wà lórí rẹ̀ àti lórí Juda àti Jerusalẹmu. 26 Nígbà náà ni Hesekiah ronúpìwàdà ní ti ìgbéraga ọkàn rẹ̀, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu sì ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí náà, ìbínú Olúwa kò wá sí orí wọn ní ìgbà àwọn ọjọ́ Hesekiah.

27 Hesekiah ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ńlá àti ọlá, ó sì ṣe àwọn ilé ìṣúra fún fàdákà àti wúrà rẹ̀ àti fún àwọn òkúta iyebíye rẹ̀, àwọn tùràrí olóòórùn dídùn àwọn àpáta àti gbogbo oríṣìí nǹkan iyebíye. 28 Ó kọ́ àwọn ilé pẹ̀lú láti tọ́jú àwọn ọkà àwọn tí wọ́n ka, ọtí tuntun àti òróró; ó sì ṣe àwọn àtíbàbà fún oríṣìí àwọn ẹran ọ̀sìn àti àwọn àṣémọ́ fun àwọn ọ̀wọ̀ ẹran. 29 Ó kọ́ àwọn ìletò, ó sì gba ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran, nítorí tí Ọlọ́run ti fún un ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ńlá.

30 Hesekiah ni ó dí ojú ìṣúra apá òkè ti orísun Gihoni. Ó sì gbe gba ìsàlẹ̀ sí ìhà ìwọ oòrùn ìlú ńlá ti Dafidi. Ó ṣe àṣeyọrí rere nínú gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé. 31 Ṣùgbọ́n nígbà tí a rán àwọn oníṣẹ́ ọba wá láti Babeli láti bi í lérè nípa ààmì ìyanu tí ó ṣẹlẹ̀ nì, Ọlọ́run fi sílẹ̀ láti dán an wò àti láti mọ gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́kàn rẹ̀.

32 Gbogbo iṣẹ́ yòókù ti ìjọba Hesekiah àti àwọn ìṣe rẹ̀, ìfarajì rẹ̀ ni a kọ sínú ìwé ìran wòlíì Isaiah ọmọ Amosi nínú ìwé àwọn ọba Juda àti Israẹli 33 Hesekiah sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín sórí òkè níbi tí àwọn ibojì àwọn àtẹ̀lé Dafidi wà. Gbogbo Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ni ó bu ọlá fún un nígbà tí ó kú. Manase ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Read full chapter

12 Gẹ́gẹ́ bí àgọ́ olùṣọ́-àgùntàn, ilé mi
    ni a ti wó lulẹ̀ tí a sì gbà kúrò lọ́wọ́ mi.
Gẹ́gẹ́ bí ahunṣọ mo ti ká ayé mi nílẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni òun sì ti ké mi kúrò lára àṣà;
    ọ̀sán àti òru ni ìwọ ṣe òpin mi.
13 Èmi fi sùúrù dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́,
    ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí kìnnìún ó ti fọ́ gbogbo egungun mi;
    ọ̀sán àti òru ni ìwọ fi ṣe òpin mi.
14 Èmi dún gẹ́gẹ́ bí àkọ̀ tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀,
    Èmi káàánú gẹ́gẹ́ bí aṣọ̀fọ̀ àdàbà.
Ojú mi rẹ̀wẹ̀sì gẹ́gẹ́ bí mo ti ń wo àwọn ọ̀run.
Ìdààmú bá mi; Ìwọ Olúwa, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi!”

15 Ṣùgbọ́n kí ni èmi lè sọ?
    Òun ti bá mi sọ̀rọ̀ àti pé òun
tìkára rẹ̀ ló ti ṣe èyí.
    Èmi yóò máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mi
    nítorí ìpọ́njú ẹ̀mí mi yìí.
16 Olúwa, nípa nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn ń gbé;
    àti pé ẹ̀mí mi rí iyè nínú wọn pẹ̀lú.
Ìwọ dá ìlera mi padà
    kí o sì jẹ́ kí n wà láààyè
17 Nítòótọ́ fún àlàáfíà ara mi ni,
    ní ti pé mo ní ìkorò ńlá.
Nínú ìfẹ́ rẹ ìwọ pa mí mọ́,
    kúrò nínú ọ̀gbun ìparun;
    ìwọ sì ti fi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.
18 Nítorí pé isà òkú kò le è yìn ọ́,
    ipò òkú kò le è kọ orin ìyìn rẹ;
àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀gbun
    kò lè ní ìrètí fún òtítọ́ rẹ.
19 Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́,
    gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí;
    àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ.

20 Olúwa yóò gbà mí là
    bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò sì kọrin pẹ̀lú ohun èlò olókùn
ní gbogbo ọjọ́ ayé wa
    nínú tẹmpili ti Olúwa.

21 Isaiah ti sọ pé, “Pèsè ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ (ohun gbígbóná tí a dì mọ́ ojú egbò) kí o sì fi sí ojú oówo náà, òun yóò sì gbádùn.”

22 Hesekiah si sọ pé, “Kí ni yóò jẹ́ ààmì pé èmi yóò gòkè lọ sí tẹmpili Olúwa?”

Àwọn ikọ̀ ọba láti Babeli

39 (A)Ní àkókò náà ni Merodaki-Baladani ọmọ Baladani ọba Babeli fi ìwé àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Hesekiah, nítorí ó gbọ́ pé ó ṣàìsàn ó sì gbádùn. Hesekiah gba àwọn ikọ̀ yìí tayọ̀tayọ̀, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà nínú yàrá ìkẹ́rù sí mọ́ hàn wọ́n—fàdákà, wúrà, ohun olóòórùn dídùn, òróró dídára, gbogbo nǹkan ogun rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìṣúra rẹ̀ kò sí ohunkóhun tí ó wà nínú ààfin rẹ̀ tàbí ní ìjọba rẹ̀ tí Hesekiah kò fihàn wọ́n.

Lẹ́yìn náà wòlíì Isaiah lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekiah ọba ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí, níbo ni wọ́n sì ti wá?”

“Láti ilẹ̀ jíjìnnà,” ni èsì Hesekiah. “Wọ́n wá sọ́dọ̀ mi láti Babeli.”

Wòlíì náà sì béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí nínú ààfin rẹ?”

Hesekiah si dáhùn pe “Wọ́n rí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin mi” ni ìdáhùn Hesekiah. “Kò sí ohun kankan nínú ìṣúra mi tí èmi kò fihàn wọ́n.”

Lẹ́yìn náà ni Isaiah sọ fún Hesekiah pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun: Àsìkò ń bọ̀ nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin rẹ, àti ohun gbogbo tí àwọn baba rẹ ti kójọ títí di ọjọ́ òní yóò di kíkó lọ sí Babeli. Ohun kankan kò ní ṣẹ́kù ni Olúwa wí. Àti díẹ̀ nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ, àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara rẹ tí a ó bí fún ọ ni a ó kó lọ, wọn yóò sì di ìwẹ̀fà nínú ààfin ọba Babeli.”

Hesekiah wí fún Isaiah pé “Rere ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ sọ,” Nítorí ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Àlàáfíà àti òtítọ́ yóò wà ní ìgbà ayé tèmi.”