Add parallel Print Page Options

Jotamu ọba Juda

27 Jotamu sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì di ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìn-dínlógún. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jeruṣa ọmọbìnrin Sadoku. Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Ussiah ti ṣe, ṣùgbọ́n kìkì wí pé kò wọ ilé Olúwa. Àwọn ènìyàn síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ibi wọn. Jotamu sì kọ́ ẹnu-ọ̀nà gíga ilé Olúwa ó sì ṣe iṣẹ́ lórí odi ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ofeli.

Read full chapter