Add parallel Print Page Options

25 (A)Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda gbé fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn ikú Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israẹli. 26 Fún ti iṣẹ́ mìíràn ti ìjọba Amasiah láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé àwọn ọba Juda àti Israẹli? 27 Láti ìgbà tí Amasiah ti yípadà kúrò láti máa tẹ̀lé Olúwa, wọ́n dìtẹ̀ sí i ní Jerusalẹmu, ó sì sálọ sí Lakiṣi ṣùgbọ́n, wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e lọ sí Lakiṣi, wọ́n sì pa á síbẹ̀. 28 A gbé e padà pẹ̀lú ẹṣin. A sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Juda.

Read full chapter