Add parallel Print Page Options

A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣùgbọ́n ara kò ni wá: a ń dààmú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù. A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀; a ń rẹ̀ wá sílẹ̀ ṣùgbọ́n a kò pa wá run. 10 Nígbà gbogbo àwa ń ru ikú Jesu Olúwa kiri ni ará wa, kí a lè fi ìyè Jesu hàn pẹ̀lú lára wa. 11 Nítorí pé nígbà gbogbo ní a ń fi àwa tí ó wà láààyè fún ikú nítorí Jesu, kí a lè fi ìyè hàn nínú ara kíkú wa pẹ̀lú.

Read full chapter

23 (A)Ìránṣẹ́ Kristi ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọpọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbàkúgbà, ní ti fífẹ́rẹ kú nígbà púpọ̀. 24 (B)Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan lọ́wọ́ àwọn Júù. 25 (C)Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú. 26 (D)Ní ìrìnàjò nígbàkúgbà, nínú ewu omi, nínú ewu àwọn ọlọ́ṣà, nínú ewu àwọn ará ìlú mi, nínú ewu àwọn aláìkọlà, nínú ewu ni ìlú, nínú ewu ní aginjù, nínú ewu lójú Òkun, nínú ewu láàrín àwọn èké arákùnrin. 27 (E)Nínú làálàá àti ìrora, nínú ìṣọ́ òru nígbàkúgbà, nínú ebi àti òǹgbẹ, nínú àwẹ̀ nígbàkúgbà, nínú òtútù àti ìhòhò.

Read full chapter