Add parallel Print Page Options

17 Ó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́jọ. 18 Ó sì rìn ní ọ̀nà ọba Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu ti lọ, nítorí ó fẹ́ ọmọbìnrin Ahabu ó sì ṣe ohun búburú níwájú Olúwa. 19 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, nítorí ti ìránṣẹ́ rẹ̀ Dafidi. Olúwa kò fẹ́ pa Juda run, ó ti ṣèlérí láti ṣètọ́jú ìmọ́lẹ̀ fún Dafidi àti àwọn ilé rẹ̀ títí láéláé.

20 Ní àsìkò Jehoramu, Edomu ṣọ̀tẹ̀ lórí Juda, ó sì jẹ́ ọba fúnrarẹ̀. 21 Bẹ́ẹ̀ ni Jehoramu lọ sí Ṣairi pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Àwọn ará Edomu sì yí i ká àti kẹ̀kẹ́ àwọn olórí wọn, ṣùgbọ́n ó dìde dúró ní òru; àwọn ogun rẹ̀ síbẹ̀síbẹ̀, sá padà lọ ilé. 22 Títí ó fi di òní, Edomu wà nínú ọ̀tẹ̀ lórí Juda, Libina ṣọ̀tẹ̀ ní àkókò kan náà.

Read full chapter