Add parallel Print Page Options

Àwọn ọmọ Dafidi

(A)Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Dafidi tí a bí fún un ní Hebroni:

Àkọ́bí sì ni Amnoni ọmọ Ahinoamu ti Jesreeli;

èkejì sì ni Daniẹli ọmọ Abigaili ará Karmeli;

Ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un;

ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti;

Ẹ̀karùnún ni Ṣefatia láti ọ̀dọ̀ Abitali;

àti ẹ̀kẹfà, Itreamu, láti ọ̀dọ̀ Egla aya rẹ̀.

(B)Àwọn mẹ́fà wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ni Hebroni, níbi tí ó ti jẹ ọba fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.

Dafidi sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33).

Read full chapter