Add parallel Print Page Options

Àwọn akọrin

25 Pẹ̀lúpẹ̀lú Dafidi àti àwọn olórí àwọn ọmọ-ogun, ó sì yà díẹ̀ sọ́tọ̀ lára àwọn ọmọ Asafu, Hemani àti Jedutuni fún ìsìn àsọtẹ́lẹ̀, pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin olókùn àti kimbali. Èyí sì ní àwọn iye àwọn ọkùnrin ẹni tí ó ṣe oníṣẹ́ ìsìn yìí:

Nínú àwọn ọmọ Asafu:

Sakkuri, Josẹfu, Netaniah àti Asarela, àwọn ọmọ Asafu ni wọ́n wà lábẹ́ ìbojútó Asafu, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀ lábẹ́ ìbojútó ọba.

Gẹ́gẹ́ bí ti Jedutuni, nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀:

Gedaliah, Seri, Jeṣaiah, Ṣimei, Haṣabiah àti Mattitiah, mẹ́fà nínú gbogbo wọn, lábẹ́ ìbojútó baba wọn Jedutuni, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀, ẹni tí ó lo dùùrù láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa:

Gẹ́gẹ́ bí ti Hemani, nínú àwọn ọmọ rẹ̀:

Bukkiah, Mattaniah, Usieli, Ṣubueli àti Jerimoti; Hananiah, Hanani, Eliata, Giddalti, àti Romamtieseri, Joṣbekaṣa, Malloti, Hotiri, Mahasiotu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Hemani àti wòlíì ọba. Wọ́n sì fi wọ́n fún nípa ìlérí Ọlọ́run láti máa gbé ìwo sókè. Ọlọ́run sì fún Hemani ní ọmọkùnrin mẹ́rìnlá àti àwọn ọmọbìnrin mẹ́ta.

Gbogbo àwọn ọkùnrin yìí ni wọ́n wà lábẹ́ ìbojútó àwọn baba wọn fún ohun èlò orin ilé Olúwa, pẹ̀lú kimbali, ohun èlò orin olókùn àti dùùrù, fún ìsìn ilé Olúwa.

Asafu, Jedutuni àti Hemani sì wà lábẹ́ ọba. Àwọn ìdílé wọn pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó mòye àti àwọn tí a kọ́ ní ohun èlò orin fún Olúwa, iye wọn sì jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó-lé-mẹ́jọ (288). Kékeré àti àgbà bákan náà, olùkọ́ àti gẹ́gẹ́ bí ti akẹ́kọ̀ọ́, ṣẹ́ kèké fún iṣẹ́ wọn.

Kèké èkínní èyí tí ó jẹ́ ti Asafu, jáde sí Josẹfu, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

èkejì sì ni Gedaliah, òun àti àwọn ìdílé rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, méjìlá

10 ẹlẹ́kẹta sí Sakkuri, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé, méjìlá

11 ẹlẹ́kẹrin sí Isiri, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

12 ẹlẹ́karùnún sí Netaniah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

13 ẹlẹ́kẹfà sí Bukkiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

14 ẹlẹ́keje sí Jasarela, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

15 ẹlẹ́kẹjọ sí Jeṣaiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

16 ẹlẹ́kẹsànán sí Mattaniah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

17 ẹlẹ́kẹwàá sí Ṣimei, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

18 ẹlẹ́kọkànlá sí Asareeli, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

19 ẹlẹ́kẹjìlá sí Haṣabiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

20 ẹlẹ́kẹtàlá sí Ṣubueli, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

21 ẹlẹ́kẹrìnlá sí Mattitiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

22 ẹlẹ́kẹdógún sí Jerimoti, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

23 ẹlẹ́kẹrìn-dínlógún sí Hananiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

24 ẹlẹ́kẹtà-dínlógún sí Joṣbekaṣa, àwọn ọmọ rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

25 ẹlẹ́kejì-dínlógún sí Hanani, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

26 ẹlẹ́kọkàndínlógún sí Malloti, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

27 ogún sí Eliata, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

28 ẹlẹ́kọkànlélógún sí Hotiri, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

29 ẹlẹ́kejìlélógún sí Giddalti, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

30 ẹlẹ́kẹtàlélógún sí Mahasiotu, àwọn ọmọ rẹ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

31 ẹlẹ́kẹrìnlélógún sí Romamtieseri àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ìdílé rẹ̀, sì jẹ́, méjìlá.

The Musicians

25 David, together with the commanders of the army, set apart some of the sons of Asaph,(A) Heman(B) and Jeduthun(C) for the ministry of prophesying,(D) accompanied by harps, lyres and cymbals.(E) Here is the list of the men(F) who performed this service:(G)

From the sons of Asaph:

Zakkur, Joseph, Nethaniah and Asarelah. The sons of Asaph were under the supervision of Asaph, who prophesied under the king’s supervision.

As for Jeduthun, from his sons:(H)

Gedaliah, Zeri, Jeshaiah, Shimei,[a] Hashabiah and Mattithiah, six in all, under the supervision of their father Jeduthun, who prophesied, using the harp(I) in thanking and praising the Lord.

As for Heman, from his sons:

Bukkiah, Mattaniah, Uzziel, Shubael and Jerimoth; Hananiah, Hanani, Eliathah, Giddalti and Romamti-Ezer; Joshbekashah, Mallothi, Hothir and Mahazioth. (All these were sons of Heman the king’s seer. They were given him through the promises of God to exalt him. God gave Heman fourteen sons and three daughters.)

All these men were under the supervision of their father(J) for the music of the temple of the Lord, with cymbals, lyres and harps, for the ministry at the house of God.

Asaph, Jeduthun and Heman(K) were under the supervision of the king.(L) Along with their relatives—all of them trained and skilled in music for the Lord—they numbered 288. Young and old alike, teacher as well as student, cast lots(M) for their duties.

The first lot, which was for Asaph,(N) fell to Joseph,
his sons and relatives[b]12[c]
the second to Gedaliah,
him and his relatives and sons12
10 the third to Zakkur,
his sons and relatives12
11 the fourth to Izri,[d]
his sons and relatives12
12 the fifth to Nethaniah,
his sons and relatives12
13 the sixth to Bukkiah,
his sons and relatives12
14 the seventh to Jesarelah,[e]
his sons and relatives12
15 the eighth to Jeshaiah,
his sons and relatives12
16 the ninth to Mattaniah,
his sons and relatives12
17 the tenth to Shimei,
his sons and relatives12
18 the eleventh to Azarel,[f]
his sons and relatives12
19 the twelfth to Hashabiah,
his sons and relatives12
20 the thirteenth to Shubael,
his sons and relatives12
21 the fourteenth to Mattithiah,
his sons and relatives12
22 the fifteenth to Jerimoth,
his sons and relatives12
23 the sixteenth to Hananiah,
his sons and relatives12
24 the seventeenth to Joshbekashah,
his sons and relatives12
25 the eighteenth to Hanani,
his sons and relatives12
26 the nineteenth to Mallothi,
his sons and relatives12
27 the twentieth to Eliathah,
his sons and relatives12
28 the twenty-first to Hothir,
his sons and relatives12
29 the twenty-second to Giddalti,
his sons and relatives12
30 the twenty-third to Mahazioth,
his sons and relatives12
31 the twenty-fourth to Romamti-Ezer,
his sons and relatives12.(O)

Footnotes

  1. 1 Chronicles 25:3 One Hebrew manuscript and some Septuagint manuscripts (see also verse 17); most Hebrew manuscripts do not have Shimei.
  2. 1 Chronicles 25:9 See Septuagint; Hebrew does not have his sons and relatives.
  3. 1 Chronicles 25:9 See the total in verse 7; Hebrew does not have twelve.
  4. 1 Chronicles 25:11 A variant of Zeri
  5. 1 Chronicles 25:14 A variant of Asarelah
  6. 1 Chronicles 25:18 A variant of Uzziel