1 Kọrinti 3:4
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
4 (A)Ǹjẹ́ ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn lásán bí? Níwọ́n ìgbà tí ẹ ba ń sọ pé, “Èmi ń tẹ̀lé Paulu,” àti ti ẹlòmíràn tún wí pé, “Èmi ń tẹ̀lé Apollo.”
Read full chapter
Ìṣe àwọn Aposteli 18:24
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
24 Júù kan sì wà tí a ń pè ni Apollo, tí a bí ni Alekisandiria, ó wá sí Efesu. Ó ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ, ó sì mọ ìwé mímọ́ púpọ̀;
Read full chapter
1 Kọrinti 3:22
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
22 (A)Ìbá ṣe Paulu, tàbí Apollo, tàbí Kefa, tàbí ayé tàbí ìyè, tàbí ikú, tàbí ohun ìsinsin yìí, tàbí ohun ìgbà tí ń bọ̀; tiyín ni gbogbo wọn.
Read full chapter
Johanu 1:42
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
42 (A)Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jesu.
Jesu sì wò ó, ó wí pé, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa ni a ó sì máa pè ọ” (ìtumọ̀ èyí tí ṣe Peteru).
Read full chapter
1 Kọrinti 9:5
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
5 (A)Ṣé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú ìyàwó tí í ṣe onígbàgbọ́ káàkiri gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli mìíràn? Àti bí arákùnrin Olúwa, àti Kefa.
Read full chapter
1 Kọrinti 15:5
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
5 (A)Àti pé ó farahàn Peteru, lẹ́yìn èyí, àwọn méjìlá
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.