Add parallel Print Page Options

31 Àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ti Lemueli ọba,

    ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ.
“Gbọ́ ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ìwọ ọmọ inú mi!
    Gbọ́ ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ́ mi.
Má ṣe lo agbára rẹ lórí obìnrin,
    okun rẹ lórí àwọn tí ó pa àwọn ọba run.

“Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lemueli
    kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnì
    kì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle
Kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wí
    kí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n
Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbé
    wáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora;
Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọn
    kí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́.

“Sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fúnrawọn
    fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹni tí ń parun
Sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbè
    jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà àti aláìní.”

10 Ta ni ó le rí aya oníwà rere?
    Ó níye lórí ju iyùn lọ
11 Ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀ nínú rẹ̀
    kò sì ṣí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀.
12 Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibi
    ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
13 Ó sa aṣọ irun àgùntàn olówùú àti ọ̀gbọ̀
    Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí.
14 Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò;
    ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn
15 Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn;
    ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀
    àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀.
16 Ó kíyèsi oko kan, ó sì rà á;
    nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin ọgbà àjàrà rẹ̀
17 Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbára tagbára
    apá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́
18 Ó rí i pé òwò òun pé
    fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú ní òru
19 Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú mú
    ó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú
20 O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà
    ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.
21 Nígbà tí òjò-dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀
    nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.
22 Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀;
    ẹ̀wù dáradára àti elése àlùkò ni aṣọ rẹ̀
23 A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibodè ìlú
    níbi tí ó ń jókòó láàrín àwọn àgbàgbà ìlú
24 Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́n
    ó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò
25 Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọ
    ó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.
26 A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n
    ìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀
27 Ó ń bojútó gbogbo ètò ilé rẹ̀
    kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́
28 Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkún
    ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un
29 “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́lá
    ṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ”
30 Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán
    nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn
31 Sì fún un ní èrè tí ó tọ́ sí i
    kí o sì jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ̀ fún un ní ìyìn ní ẹnu ibodè ìlú.