Add parallel Print Page Options

14 Nígbà ti wọ́n sì là Perga kọjá, wọ́n wá sí Pisidia ní Antioku. Wọ́n sì wọ inú Sinagọgu ní ọjọ́ ìsinmi, wọ́n sì jókòó. 15 Lẹ́yìn kíka ìwé òfin àti ìwé àwọn wòlíì, àwọn olórí Sinagọgu ránṣẹ́ sí wọn, pé, “Ará, bí ẹ̀yin bá ni ọ̀rọ̀ ìyànjú kan fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́!”

16 Paulu sì dìde dúró, ó sì juwọ́ sí wọn, ó ní, “Ẹ̀yin Israẹli, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ fi etí sílẹ̀ sí mi! 17 (A)Ọlọ́run àwọn ènìyàn Israẹli yìí yan àwọn baba wa, ó sì gbé àwọn ènìyàn náà lékè, nígbà tí wọ́n ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Ejibiti, pẹ̀lú agbára ńlá ni ó sì fi mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀, 18 (B)ní ìwọ̀n ìgbà ogójì ọdún ni ó fi mú sùúrù fún ìwà wọn ní ijù, 19 (C)nígbà tí ó sì ti run orílẹ̀-èdè méje ni ilẹ̀ Kenaani, ó sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ni ìní. 20 Gbogbo èyí sì ṣẹlẹ̀ fún ìwọ̀n àádọ́ta-lé-ní-irínwó (450) ọdún.

“Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run fi onídàájọ́ fún wọn, títí ó fi di ìgbà Samuẹli wòlíì. 21 Lẹ́yìn náà ni wọ́n sì béèrè ọba; Ọlọ́run sì fún wọn ní Saulu ọmọ Kiṣi, ọkùnrin kan nínú ẹ̀yà Benjamini, fún ogójì ọdún. 22 (D)Nígbà ti ó sì mú Saulu kúrò, ó gbé Dafidi dìde ní ọba fún wọn, ẹni tí ó sì jẹ́rìí rẹ̀ pé, ‘Mo rí Dafidi ọmọ Jese ẹni bí ọkàn mi, ti yóò ṣe gbogbo ìfẹ́ mi.’

23 “Láti inú irú-ọmọ ọkùnrin yìí ni Ọlọ́run ti gbé Jesu Olùgbàlà dìde fún Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìlérí. 24 (E)Ṣáájú wíwá Jesu ni Johanu ti wàásù bamitiisi ìrònúpìwàdà fún gbogbo ènìyàn Israẹli. 25 (F)Bí Johanu sì ti ńlá ipa tirẹ̀ já, ó ni, ‘Ta ni ẹ̀yin ṣe bí èmi jẹ́? Èmi kì í ṣe òun. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsi í, ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú.’

26 (G)“Ará, ẹ̀yin ọmọ ìran Abrahamu, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa ni a rán ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí sí. 27 Nítorí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu, àti àwọn olórí wọn, nítorí tiwọn kò mọ̀ Jesu, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi. 28 Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pilatu láti pa á. 29 Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀wé nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì. 30 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, 31 o sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Galili wá sí Jerusalẹmu, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsin yìí fún àwọn ènìyàn.

32 “Àwa sì mú ìhìnrere wá fún yín pé: Ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa, 33 (H)èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jesu dìde: Bí a sì ti kọ̀wé rẹ̀ nínú Saamu kejì pé:

“ ‘Ìwọ ni Ọmọ mi;
    lónìí ni mo bí ọ.’

34 (I)Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyìí pé:

“ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dafidi, tí ó dájú.’

35 (J)Nítorí ó sì wí nínú Saamu mìíràn pẹ̀lú pé:

“ ‘Ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.’

36 “Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dafidi ti sin ìran rẹ tan nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́. 37 Ṣùgbọ́n ẹni tí Ọlọ́run jí dìde kò rí ìdíbàjẹ́.

38 “Ǹjẹ́ kí ó yé yín, ará pé nípasẹ̀ Jesu yìí ni a ń wàásù ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín. 39 Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mose. 40 Nítorí náà, ẹ kíyèsára, kí èyí tí a ti sọ nínú ìwé àwọn wòlíì má ṣe dé bá yín pé:

41 (K)“ ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,
    kí ẹnu sì yà yín, kí a sì fẹ́ yín kù;
nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín,
    tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́,
    bí a tilẹ̀ sọ fún yin.’ ”

42 Bí Paulu àti Barnaba sì ti ń jáde láti inú Sinagọgu, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí a sọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i fún wọn lọ́jọ́ ìsinmi tí ń bọ̀. 43 Nígbà tí wọn sì jáde nínú Sinagọgu, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù àti nínú àwọn olùfọkànsìn aláwọ̀ṣe Júù tẹ̀lé Paulu àti Barnaba, àwọn ẹni tí ó bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì rọ̀ wọ́n láti dúró nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

44 Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, gbogbo ìlú sí fẹ́rẹ̀ péjọ tan láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. 45 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù rí ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, wọ́n kún fún owú, wọ́n ń sọ̀rọ̀-òdì sí ohun ti Paulu ń sọ.

46 Paulu àti Barnaba sì dá wọn lóhùn láìbẹ̀rù pé, “Ẹ̀yin ni ó tọ́ sí pé ki a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti ta á nù, tí ẹ sì ka ara yín sí aláìyẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó, àwa yípadà sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà. 47 (L)Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ṣa ti pàṣẹ fún wa pé:

“ ‘Mo ti gbé ọ kalẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà,
    kí ìwọ lè mú ìgbàlà wá títí dé òpin ayé.’ ”

48 Nígbà tí àwọn aláìkọlà sì gbọ́ èyí, wọ́n sì yín ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lógo: gbogbo àwọn tí a yàn sí ìyè àìnípẹ̀kun sì gbàgbọ́.

49 A sí tan ọ̀rọ̀ Olúwa ká gbogbo agbègbè náà. 50 Ṣùgbọ́n àwọn Júù rú àwọn obìnrin olùfọkànsìn àti ọlọ́lá sókè àti àwọn àgbà ìlú náà, wọ́n sì gbé inúnibíni dìde sí Paulu àti Barnaba, wọ́n sì le wọn kúrò ni agbègbè wọn. 51 Ṣùgbọ́n wọ́n gbọn eruku ẹsẹ̀ wọn sí wọn, wọn sì wá sí Ikoniomu. 52 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn si kún fún ayọ̀ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́.

Read full chapter

Ní Ikoniomu

14 Ó sí ṣe, ni Ikoniomu, Paulu àti Barnaba jùmọ̀ wọ inú Sinagọgu àwọn Júù lọ, wọ́n sì sọ̀rọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù àti àwọn Helleni gbàgbọ́, Ṣùgbọ́n àwọn aláìgbàgbọ́ Júù rú ọkàn àwọn aláìkọlà sókè, wọ́n sì mú wọn ni ọkàn ìkorò sí àwọn arákùnrin náà. Nítorí náà Paulu àti Barnaba gbé ibẹ̀ pẹ́, wọ́n ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú Olúwa, ẹni tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, ó sì mu kí iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu máa ti ọwọ́ wọn ṣe. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà pín sí méjì: apá kan dàpọ̀ mọ́ àwọn Júù, apá kan pẹ̀lú àwọn aposteli. Bí àwọn aláìkọlà, àti àwọn Júù pẹ̀lú àwọn olórí wọn ti fẹ́ kọlù wọ́n láti fi àbùkù kàn wọ́n, àti láti sọ wọ́n ní òkúta, wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì sálọ sí Lysra, àti Dabe, àwọn ìlú Likaonia àti sí agbègbè àyíká. Níbẹ̀ ni wọ́n sì ń wàásù ìhìnrere.

Ní Lysra àti Dabe

Ọkùnrin kan sí jókòó ni Lysra, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò mókun, arọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí kò rìn rí. Ọkùnrin yìí gbọ́ bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀: ẹni, nígbà tí ó tẹjúmọ́ ọn ti ó sì rí i pé, ó ni ìgbàgbọ́ fún ìmúláradá. 10 Ó wí fún un ní ohùn rara pé, “Dìde dúró ṣánṣán lórí ẹsẹ̀ rẹ!” Ó sì ń fò sókè, ó sì ń rìn.

11 Nígbà tí àwọn ènìyàn sì rí ohun tí Paulu ṣe, wọ́n gbé ohùn wọn sókè ni èdè Likaonia, wí pé, “Àwọn ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wá wá ni àwọ̀ ènìyàn!” 12 Wọn sì pe Barnaba ni Seusi àti Paulu ni Hermesi nítorí òun ni olórí ọ̀rọ̀ sísọ. 13 Àlùfáà Seusi, ẹni ti ilé òrìṣà rẹ̀ wá lẹ́yìn odi ìlú wọn sì mú màlúù àti màrìwò wá sí ẹnu ibodè láti rú ẹbọ pẹ̀lú ìjọ ènìyàn sí àwọn aposteli wọ̀nyí.

14 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn aposteli Barnaba àti Paulu gbọ́, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọn sí súré wọ inú àwùjọ, wọn ń ké rara pé: 15 (A)“Ará, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ènìyàn bí ẹ̀yin náà ni àwa ń ṣe pẹ̀lú, ti a sì ń wàásù ìhìnrere fún yín, kí ẹ̀yin ba à lè yípadà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sí Ọlọ́run alààyè, tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn. 16 Ní ìran tí ó ti kọjá, ó faradà á fún gbogbo orílẹ̀-èdè, láti máa rìn ni ọ̀nà tiwọn. 17 Ṣùgbọ́n kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní àìní ẹ̀rí, ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín lójò láti ọ̀run wá, àti ni àkókò èso, ó ń fi oúnjẹ àti ayọ̀ kún ọkàn yín.” 18 Díẹ̀ ni ó kù kí wọn má le fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ènìyàn dúró, kí wọn má ṣe rú ẹbọ bọ wọ́n.

19 (B)Àwọn Júù kan sì ti Antioku àti Ikoniomu wá, nígbà tí wọ́n yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà, wọ́n sì sọ Paulu ní òkúta, wọ́n wọ́ ọ kúrò sí ẹ̀yin odi ìlú náà, wọn ṣe bí ó ti kú. 20 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn dúró ti i yíká, ó dìde ó sì padà wọ inú ìlú náà lọ. Ní ọjọ́ kejì ó bá Barnaba lọ sí Dabe.

Read full chapter

Timotiu darapọ̀ mọ́ Paulu àti Sila

16 Ó sì wá sí Dabe àti Lysra: sí kíyèsi i, ọmọ-ẹ̀yìn kan wà níbẹ̀, tí a ń pè ní Timotiu, ọmọ obìnrin kan tí í ṣe Júù, tí ó gbàgbọ́; ṣùgbọ́n Giriki ní baba rẹ̀. Ẹni tí a ròhìn rẹ̀ ní rere lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin tí ó wà ní Lysra àti Ikoniomu. Òun ni Paulu fẹ́ kí ó bá òun lọ; ó sì mú un, ó sì kọ ọ́ ní ilà, nítorí àwọn Júù tí ó wà ní agbègbè wọ̀nyí: nítorí gbogbo wọn mọ̀ pé, Giriki ni baba rẹ̀. Bí wọn sì ti ń la àwọn ìlú lọ, wọ́n ń fi àwọn àṣẹ, tí a tí pinnu láti ọ̀dọ̀ àwọn aposteli àti àwọn alàgbà tí ó wà ní Jerusalẹmu, lé wọn lọ́wọ́ láti máa pa wọ́n mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ sì fẹsẹ̀múlẹ̀ ní ìgbàgbọ́, wọn sí ń pọ̀ sí i ní iye lójoojúmọ́.

Read full chapter