Luku 23:22
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
22 Ó sì wí fún wọn lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, “Èéṣe, búburú kín ni ọkùnrin yìí ṣe? Èmi kò rí ọ̀ràn ikú lára rẹ̀: nítorí náà èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀.”
Read full chapter
Johanu 19:12-14
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
12 (A)Nítorí èyí, Pilatu ń wá ọ̀nà láti dá a sílẹ̀: ṣùgbọ́n àwọn Júù kígbe, wí pé, “Bí ìwọ bá dá ọkùnrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Kesari: ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ara rẹ̀ ní ọba, ó sọ̀rọ̀-òdì sí Kesari.”
13 Nítorí náà nígbà tí Pilatu gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Jesu jáde wá, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ ní ibi tí a ń pè ní Òkúta-títẹ́, ṣùgbọ́n ní èdè Heberu, Gabata. 14 (B)Ó jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ àjọ ìrékọjá, ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí ẹ̀kẹfà:
Ó sì wí fún àwọn Júù pé, “Ẹ wo ọba yín!”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.