Add parallel Print Page Options

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. b Orin.

46 Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa
    ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.
Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,
    tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.
Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì
    tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela.

Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn,
    ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.
Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀:
    Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.
Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú,
    ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.

Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa,
    Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.

Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa
    irú ahoro tí ó ṣe ní ayé.
O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé
    ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì
ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná
10 Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run.
A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè
    A ó gbé mi ga ní ayé.

11 Ọlọ́run alágbára wà pẹ̀lú wa
    Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.