Add parallel Print Page Options

Àkàrà lórí omi

11 Fún àkàrà rẹ sórí omi,
    nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò rí i padà
Fi ìpín fún méje, àní fún mẹ́jọ pẹ̀lú,
    nítorí ìwọ kò mọ ohun ìparun tí ó le è wá sórí ilẹ̀.

Bí àwọsánmọ̀ bá kún fún omi,
    ayé ni wọ́n ń rọ òjò sí
Bí igi wó sí ìhà gúúsù tàbí sí ìhà àríwá
    níbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn;
    ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo àwọsánmọ̀ kò ní kórè.

Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́
    tàbí mọ bí ọmọ tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀,
bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́run
    ẹlẹ́dàá ohun gbogbo.

Fún irúgbìn rẹ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù,
    má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣọlẹ̀ ní àṣálẹ́,
nítorí ìwọ kò mọ èyí tí yóò ṣe rere
    bóyá èyí tàbí ìyẹn
    tàbí àwọn méjèèjì ni yóò ṣe dáradára bákan náà.

Rántí ẹlẹ́dàá rẹ ní ìgbà èwe rẹ

Ìmọ́lẹ̀ dùn;
    Ó sì dára fún ojú láti rí oòrùn.
Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn jẹ̀gbádùn gbogbo iye ọdún
    tí ó le è lò láyé
ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó rántí ọjọ́ òkùnkùn
    nítorí wọn ó pọ̀
    Gbogbo ohun tí ó ń bọ̀ asán ni.

Jẹ́ kí inú rẹ dùn, ìwọ ọ̀dọ́mọdé ní ìgbà tí o wà ní èwe
    kí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ fún ọ ní ayọ̀ ní ìgbà èwe rẹ.
Tẹ̀lé ọ̀nà ọkàn rẹ
    àti ohunkóhun tí ojú rẹ rí
ṣùgbọ́n mọ̀ dájú pé nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni
    Ọlọ́run yóò mú ọ wá sí ìdájọ́.
10 Nítorí náà, mú ìjayà kúrò ní ọkàn rẹ
    kí o sì lé ìbànújẹ́ ara rẹ kúrò
    nítorí èwe àti kékeré kò ní ìtumọ̀.