Add parallel Print Page Options

Ẹ̀bẹ̀ àdúrà

(A)Ní àkótán, ará, ẹ máa gbàdúrà fún wa, kí ọ̀rọ̀ Olúwa lè máa tàn káàkiri, kí ó sì jẹ́ èyí tí a bu ọlá fún, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọ̀dọ̀ yín. (B)Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún wa kí a lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìkà àti àwọn ènìyàn búburú, nítorí pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló ní ìgbàgbọ́. (C)Ṣùgbọ́n olódodo ni Olúwa, ẹni tí yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóò sì pa yín mọ́ kúrò nínú ibi. Àwa sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ní ti ohun tí ẹ ń ṣe, àti pé àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a pàṣẹ fún un yín ni ẹ̀yin ń ṣe. Kí Olúwa máa tọ́ ọkàn yín ṣọ́nà sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti sínú sùúrù Kristi.

Ìkìlọ̀ ní ṣíṣe ìmẹ́lẹ́

(D)Ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wa, àwa pàṣẹ fún un yín ará, pé kí ẹ yẹra fún gbogbo àwọn arákùnrin yín tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́, tí kò sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí ẹ gbà ní ọ̀dọ̀ wa. (E)Nítorí ẹ̀yin náà mọ̀ bí ó ṣe yẹ kí ẹ máa fi ara wé wa. Àwa kì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nígbà tí a wà ní ọ̀dọ̀ yín. (F)Bẹ́ẹ̀ ni àwa kò sì jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, àwa ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru kí a má ba à di àjàgà sí ẹnikẹ́ni nínú yín lọ́rùn. (G)Àwa ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, kì í ṣe nítorí pé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti béèrè fún un, ṣùgbọ́n àwa ń fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ tí ẹ ó tẹ̀lé. 10 (H)Nítorí nígbà tí àwa wà lọ́dọ̀ yín, a ṣe àwọn òfin wọ̀nyí fún un yín pé, “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.”

11 (I)A gbọ́ pé àwọn kan wà láàrín yín tí wọn jẹ́ ìmẹ́lẹ́. Wọ́n jẹ́ atọjúlékiri. 12 (J)Ǹjẹ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa ń pàṣẹ fún, tí a sì ń rọ̀ nínú Jesu Kristi Olúwa pé kí wọn ó máa ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ. 13 (K)Ṣùgbọ́n ní tiyín ará, ẹ má ṣe jẹ́ kí agara dá yín ní rere ṣíṣe.

14 Bí ẹnikẹ́ni kò bá sì pa òfin wa nínú lẹ́tà yìí mọ́, ẹ ṣààmì sí ẹni náà. Ẹ má ṣe bá a kẹ́gbẹ́ kí ojú bà á le tì í. 15 Síbẹ̀, ẹ má ṣe kà á sí ọ̀tá, ṣùgbọ́n ẹ máa kìlọ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí arákùnrin yín.

Ìkíni ìkẹyìn

16 (L)Ǹjẹ́ kí Olúwa àlàáfíà, fúnrarẹ̀ máa fún yín ní àlàáfíà nígbà gbogbo. Kí Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín.

17 (M)Èmi Paulu fi ọwọ́ ara mi kọ lẹ́tà ìkíni yìí, èyí ṣe ààmì ìdámọ̀ nínú gbogbo lẹ́tà. Bí mo ṣe máa ń kọ̀wé nìyìí.

18 (N)Kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa wà pẹ̀lú yín.