Add parallel Print Page Options

29 Ẹni tí ó sì ń ṣorí kunkun lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí
    yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.

Nígbà tí olódodo bá ń gbilẹ̀, àwọn ènìyàn a yọ̀
    nígbà tí ènìyàn búburú ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn ń kórìíra.

Ènìyàn tí ó fẹ́ràn ọgbọ́n mú kí baba rẹ̀ láyọ̀
    ṣùgbọ́n ẹni ti ń bá panṣágà kẹ́gbẹ́ ba ọrọ̀ ọ rẹ̀ jẹ́.

Nípa ìdájọ́ òdodo ni ọba fi í mú ìlú tòrò nini,
    ṣùgbọ́n èyí tí ń ṣe ojúkòkòrò àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fà á lulẹ̀.

Ẹnikẹ́ni tí ó bá tan aládùúgbò rẹ̀
    ó ń dẹ àwọ̀n de ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀.

Ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn ibi ni ó jẹ́ ìdẹ̀kùn rẹ̀
    ṣùgbọ́n olódodo le è kọrin kí ó sì máa yọ̀.

Olódodo ń máa ro ọ̀rọ̀ tálákà,
    ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kò sú sí i láti rò ó.

Àwọn ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè,
    ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò.

Bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn bá lọ sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aláìgbọ́n
    aláìgbọ́n a máa bínú a sì máa jà, kò sì ní sí àlàáfíà.

10 Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kò rí ẹni dídúró ṣinṣin
    wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo.

11 Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹnu rẹ̀ bínú
    ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu.

12 Bí olórí bá fetí sí irọ́,
    gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀.

13 Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí,
    Olúwa jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran.

14 Bí ọba kan bá ń ṣe ìdájọ́ tálákà pẹ̀lú òtítọ́
    ìtẹ́ ìjọba rẹ yóò fìdímúlẹ̀ nígbà gbogbo.

15 Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́n
    ṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnrarẹ̀ a dójútì ìyá rẹ̀.

16 Nígbà tí ènìyàn búburú ń gbilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ ń gbilẹ̀
    ṣùgbọ́n olódodo yóò rí ìṣubú wọn.

17 Bá ọmọ rẹ wí, yóò sì fún ọ ní àlàáfíà
    yóò sì mú inú dídùn wá sí inú ọkàn rẹ.

18 Níbi tí kò ti sí ìfihàn, àwọn ènìyàn a gbé ìgbé ayé àìbìkítà,
    ṣùgbọ́n ìbùkún ní fún àwọn tí ń pa òfin mọ́.

19 A kò le fi ọ̀rọ̀ lásán kìlọ̀ fún ìránṣẹ́
    bí ó tilẹ̀ yé e, kò ní kọbi ara sí i.

20 Ǹjẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀?
    Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ.

21 Bí ènìyàn kan bá kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lákẹ̀ẹ́jù láti kékeré
    yóò mú ìbànújẹ́ wá ní ìgbẹ̀yìn.

22 Oníbìínú ènìyàn a ru ìjà sókè,
    onínú-fùfù ènìyàn a sì máa dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀.

23 Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀
    ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì.

24 Ẹni tí ó ń kó ẹgbẹ́, olè kórìíra ọkàn ara rẹ̀,
    ó ń gbọ́ èpè olóhun kò sì le è fọhùn.

25 Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹ̀kùn
    ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù Olúwa wà láìléwu.

26 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ń wá ojúrere alákòóso,
    ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ènìyàn tí ń gba ìdájọ́ òdodo.

27 Olódodo kórìíra àwọn aláìṣòótọ́:
    ènìyàn búburú kórìíra olódodo.