Add parallel Print Page Options

27 Má ṣe yangàn nítorí ọ̀la
    nítorí o kò mọ ohun tí ọjọ́ kan le è mú wáyé.

Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹ
    àní àlejò, kí ó má sì ṣe ètè ìwọ fúnrarẹ̀.

Òkúta wúwo, erùpẹ̀ sì wúwo
    ṣùgbọ́n ìbínú aṣiwèrè wúwo ju méjèèjì lọ.

Ìbínú ni ìkà, ìrunú sì burú púpọ̀
    ṣùgbọ́n ta ni ó le è dúró níwájú owú?

Ìbániwí gbangba sàn
    ju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ.

Òtítọ́ ni ọgbẹ́ ọ̀rẹ́,
    ṣùgbọ́n ìfẹnukonu ọ̀tá ni ẹ̀tàn.

Kódà oyin kò dùn lẹ́nu ẹni tí ó ti yó
    ṣùgbọ́n òróǹró gan an dùn lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.

Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀
    ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀.

Ìpara olóòórùn dídùn àti tùràrí ń mú ayọ̀ wá sínú ọkàn
    bẹ́ẹ̀ ni inú dídùn láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń wá láti inú ìmọ̀ràn tí ó ṣàkóso.

10 Má ṣe kọ ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ baba rẹ sílẹ̀,
    má sì ṣe lọ sílé arákùnrin rẹ nígbà tí ìdààmú dé bá ọ
    ó sàn kí o jẹ́ aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni ju arákùnrin tí ó jìnnà sí ni.

11 Gbọ́n, ọmọ mi, kí o sì mú ayọ̀ wá sínú ọkàn mi
    nígbà náà ni mo le dá gbogbo ẹni tí ó bá kẹ́gàn mi.

12 Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fi ara pamọ́
    ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí, kàkà kí ó dúró ó tẹ̀síwájú, ó sì jìyà rẹ̀.

13 Gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àjèjì
    fi ṣe ẹ̀rí ìdúró bí o bá ṣe onídùúró fún obìnrin oníṣekúṣe.

14 Bí ènìyàn kan ń kígbe súre fún aládùúgbò rẹ ní òwúrọ̀
    a ó kà á sí bí èpè.

15 Àyà tí ó máa ń jà dàbí
    ọ̀wààrà òjò ní ọjọ́ tí òjò ń rọ̀;
16 dídá a lẹ́kun dàbí ìgbà tí ènìyàn ń dá afẹ́fẹ́ lẹ́kun
    tàbí bí ẹni tí ó gbá òróró.

17 Bí irin tí ń pọ́n irin mú
    bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú.

18 Ẹni tí ó tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóò jẹ èso rẹ̀
    ẹni tí ó sì fojú tó ọ̀gá rẹ̀ yóò gba ọlá.

19 Bí omi tí ń ṣe àfihàn ojú, nígbà tí a bá wò ó
    bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ènìyàn ń ṣe àfihàn ènìyàn.

20 Kò tẹ́ ikú àti ìparun lọ́rùn rí
    bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ojú ènìyàn kò rí ìtẹ́lọ́rùn rí.

21 Iná fún fàdákà iná ìléru fún wúrà,
    ṣùgbọ́n a ń dán ènìyàn wò nípa ìyìn tí ó ń gbà.

22 Bí a tilẹ̀ gún aláìgbọ́n nínú odó,
    fi ọmọ odó gún un bí èlùbọ́
    ìwọ kì yóò le è yọ ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ kúrò ní inú rẹ̀.

23 Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wà
    bojútó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára;
24 Nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí
    adé kì í sì í wà lórí títí láéláé.

25 Nígbà tí a bá kó koríko, ewéko tuntun yóò sì hù jáde, a ó sì kó koríko àwọn orí òkè wọlé
26 àwọn àgùntàn yóò pèsè aṣọ fún ọ,
    àti ewúrẹ́ yóò pèsè owó oko.

27 Ìwọ yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà ewúrẹ́
    láti bọ́ ọ àti ìdílé rẹ
    àti láti tọ́jú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.