Add parallel Print Page Options

24 Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburú
    má ṣe jẹ́ kí àwùjọ wọn wù ọ́;
Nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ohun búburú,
    ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ nípa dídá rúgúdù sílẹ̀.

Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́
    nípa òye sì ni ó ti fìdímúlẹ̀;
Nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kún
    pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n.

Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára púpọ̀,
    ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń ní agbára sí i
Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà:
    nínú ìṣẹ́gun ni ọ̀pọ̀ onígbìmọ̀.

Ọgbọ́n ga ju fún aṣiwèrè
    àti gbọ̀ngàn ìlú níbi ibodè kò ní ohun tí yóò wí.

Ẹni tí ń pète ibi
    ni a ó mọ̀ bí ènìyàn ibi.
Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
    àwọn ènìyàn sì kórìíra ẹlẹ́gàn.

10 Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmú
    báwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó!
11 Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ sí ibi ikú là;
    fa àwọn tó ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lọ sí ibi ìparun padà.
12 Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkan kan nípa èyí,”
    ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsi i? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́n?
    Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe?

13 Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára,
    oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu.
14 Mọ̀ pẹ̀lú pé ọgbọ́n pẹ̀lú dùn fún ọkàn rẹ
    bí ìwọ bá rí i ìrètí ọjọ́ iwájú wà fún ọ
    ìrètí rẹ kì yóò sì já ṣófo.

15 Má ṣe ba ní ibùba bí ènìyàn búburú
    láti gba ibùjókòó olódodo,
    má ṣe fi ibi ìsinmi rẹ̀ ṣe ìjẹ;
16 nítorí bí olódodo ènìyàn bá tilẹ̀ ṣubú ní ìgbà
    méje, yóò tún padà dìde sá á ni,
    ṣùgbọ́n ìdààmú yóò fa ènìyàn búburú lulẹ̀.

17 Má ṣe yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú;
nígbà tí ó bá kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yọ̀.
18 Àìṣe bẹ́ẹ̀ Olúwa yóò rí i yóò sì bínú
    yóò sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

19 Má ṣe fòyà nítorí àwọn ènìyàn ibi
    tàbí jowú àwọn ènìyàn búburú,
20 nítorí ẹni ibi kò ní ìrètí ọjọ́ iwájú
    a ó sì pa fìtílà àwọn ènìyàn búburú kú.

21 Bẹ̀rù Olúwa àti ọba, ọmọ mi,
    má sì ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí kunkun.
22 Nítorí àwọn méjèèjì yóò rán ìparun òjijì sórí wọn,
    ta ni ó sì mọ irú ìyọnu tí wọ́n lè mú wá?

Àwọn ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n mìíràn

23 Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n:

    láti ṣe ojúsàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá:
24 Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, “Ìwọ lo jàre”
    àwọn ènìyàn yóò ṣẹ́ èpè fún un àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì kọ̀ ọ́.
25 Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi,
    ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn.

26 Ìdáhùn òtítọ́
    dàbí ìfẹnu-koni-ní-ẹnu.

27 Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹ
    sì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára;
    lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.

28 Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládùúgbò rẹ láìnídìí,
    tàbí kí o fi ètè rẹ tannijẹ.
29 Má ṣe wí pé, “Èmi yóò ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi;
    Èmi yóò san ohun tí ó ṣe fún mi padà fún un.”

30 Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ,
    mo kọjá níbi ọgbà àjàrà aláìgbọ́n ènìyàn;
31 ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo,
    koríko ti gba gbogbo oko náà
32 Mo fi ọkàn mi sí nǹkan tí mo kíyèsi
    mo sì kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí mo rí;
33 oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,
    ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi
34 Òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalè
    àti àìní bí olè.