Add parallel Print Page Options

20 Ẹlẹ́yà ni ọtí wáìnì, aláriwo sì ní ọtí líle
    ẹnikẹ́ni tí ó bá fi tànjẹ kò gbọ́n.

Ìbẹ̀rù ọba dàbí kíké e kìnnìún;
    ẹnikẹ́ni tí ó bá mú un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́.

Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà,
    ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà.

Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ,
    nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.

Ète ọkàn ènìyàn dàbí omi jíjìn;
    ṣùgbọ́n ènìyàn olóye á wá wọn jáde.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń sọ pe àwọn ní ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn,
    ṣùgbọ́n kò rọrùn láti rí ènìyàn olóòtítọ́.

Olódodo ènìyàn a máa gbé ìgbé ayé àìlábùkù
    ìbùkún ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.

Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́
    yóò fẹ́ gbogbo ibi dànù pẹ̀lú ojú rẹ̀.

Ta ni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́,
    mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”?

10 Ìwọ̀n èké àti òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ
    Olúwa kórìíra méjèèjì.

11 Kódà a mọ ọmọdé nípa iṣẹ́ rẹ̀
    nípa pe bóyá iṣẹ́ rẹ mọ́ tàbí pé ó tọ̀nà.

12 Etí tí ó ń gbọ́ àti ojú tí ó ń ríran
    Olúwa ni ó dá méjèèjì.

13 Má ṣe fẹ́ràn oorun, àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò di tálákà.
    Ma ṣe sùn ìwọ yóò sì ní oúnjẹ láti tún fi tọrọ.

14 “Kò dára, kò dára” ní ẹni tó ra ọjà máa ń wí
    nígbà tí ó bá kúrò níbẹ̀ tán,
    yóò máa yangàn bí òun tí ṣe rí rà sí.

15 Wúrà wà, iyùn sì wà rẹpẹtẹ
    ṣùgbọ́n, ahọ́n tí ń sọ ìmọ̀ gan an ni ọ̀ṣọ́ iyebíye.

16 Gba abọ́ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àlejò;
    mú un lọ́wọ́ bí ìbúra bí ó bá ṣe é fún obìnrin onírìnkurìn.

17 Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà èrú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn
    ṣùgbọ́n, a yọrí sí ibi ẹnu tí ó kún fún erùpẹ̀.

18 Pa ètè rẹ mọ́ nípa wíwá ìmọ̀ràn
    bí o bá ń jagun, gba ìtọ́sọ́nà.

19 Olófòófó a máa tú àṣírí
    nítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ púpọ̀.

20 Bí ènìyàn kan bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀,
    ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ni a ó pa kú nínú òkùnkùn biribiri.

21 Ogún tí a kójọ kíákíá ní ìbẹ̀rẹ̀
    kì yóò ní ìbùkún ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín.

22 Má ṣe wí pé, “N ó ṣẹ̀san àṣìṣe rẹ yìí fún ọ”
    Dúró de Olúwa yóò sì gbà ọ́ là.

23 Olúwa kórìíra òdínwọ̀n èké.
    Òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.

24 Olúwa ni ó ń ṣe olùdarí ìgbésẹ̀ ènìyàn
    Báwo wá ni òye gbogbo ọ̀nà ènìyàn ṣe le yé ni?

25 Ìdẹ̀kùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíá
    nígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò.

26 Ọlọ́gbọ́n ọba tú ènìyàn búburú ká;
    Ó sì fi òòlọ ìpakà lọ̀ wọ́n.

27 Àtùpà Olúwa ń ṣe àwárí ẹ̀mí ènìyàn
    a máa ṣàwárí ibi ìkọ̀kọ̀ inú.

28 Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́,
    nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu.

29 Ògo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ni agbára wọn,
    ewú orí ni iyì arúgbó.

30 Ìgbájú ìgbámú àti ìfarapa máa ń mú ibi lọ,
    pàṣán sì máa ń ṣe àfọ̀mọ́ ibi ìkọ̀kọ̀ inú.